Ó yá, ẹni ọkan mi,
tẹ́'wọ àdúra:
Mo gba àdúrà yi fún o ati fun gbogbo idile re ni odun 2017 yi wípé l'ónìí àti l'ójó gbogbo...
▫Ojú kò ní tì e.
▫Ayé kò ní yò e.
▫Olórun kò ní gba ògo re fún elòmíràn láéláé.
▫Igbá ilé re kò ní fó.
▫Aso ìbora re kò ní fà ya.
▫Ayé kò ní da àbàwón sí aso re.
▫Àgbá omi re kò ní gbe.
▫Kókóró ayò re kò ní bá omi lo.
▫Bí o bá n taá, á máa jó.
▫Bí o bá n lùú, á máa dún.
▫Abéré olóore re kò ni bó s'ómi.
▫Omo aráyé kò ní fi ire tìre se àpínle.
▫Bí ó ti wù kí ilé ìwòsån dára tó, oò nì fi ibe se ibùgbé.
▫Bí ó ti wù kí aso èwòn l'éwà tó, oò ní bá won wò ní'bè .
▫Won o ní fi èjè re se ìrúbo.
▫Ohun tí omo aráyé kò fi pamó sí o l'ówó, won kò ní bèèrè re l'ówóo re.
▫Omo aráyé kò ní fi egba fún o l'óúnje.
▫Bí ó ti wù kí àná ati òní re dára tó, òla re yóó l'éwà ju gbogbo won lo.
▫Orí re kò ní burú; èdá re kò ní gb'àbòdè
▫Gbogbo ibití elégbé re bá ti n ná owó, o kò ní bá won ná aájò nibe.
▫Oò ní se àsetì.
▫Wa á lu àlùyo.
▫Omo aráyé kò ní bó bàtà òfò si enu ònà iléè re.....
🏳 Aaaamin l'agbara Eledumare!
Asiko yi a tuwa lara
Ireti wa ko ni ja s'ofo.
Gbogbo igi ti elegbede ba fowo lu didun lo ndun...
▫Gbogbo adawole re yo yori si rere.
▫Gbogbo owo ti ogede ba na soke, ara re lo nfi lu kehin. Enikeni, edakeda, eeyan-keeyan ti abi ninu obinrin, abi ti a fabe gbebi e, to ba ro ibi ro e, ko fi ori ara re gbe.
▫Ilekun aanu ko ni ti mo e.
▫Ibukun ati alafia ti aye kole jakule ni yoo je ipin re.
▫Oju owo ko ni pon e.
▫Oro re yo dayo.
🏳Emi wa a se opolopo Odun laye. Amin.
2017 odun ayo ni Olorun yio ṣe kale ooo. Owo wa a to eti, okan wa abale o.
Ọ̀rọ̀ jade, Àṣẹ gun!
Today, God will visit your home - On His way out, He will take all your problems with Him. Amen```
![image](https://img.esteem.ws/rwqngaig7i.jpg)
_
Amin. Thank you sir
Downvoting a post can decrease pending rewards and make it less visible. Common reasons:
Submit
olorun ko ni gbagbe iwo naa ooooo
Downvoting a post can decrease pending rewards and make it less visible. Common reasons:
Submit