ORIKI IBADAN
Ibadan mesi Ogo, nile Oluyole. Ilu Ogunmola, olodogbo keri loju ogun. Ilu Ibikunle alagbala jaya-jaya. Ilu Ajayi, o gbori Efon se filafila. Ilu Latosa, Aare-ona kakanfo. Ibadan Omo ajoro sun. Omo a je Igbin yoo,fi ikarahun fo ri mu. Ibadan maja-maja bii tojo kin-in-ni, eyi too ja aladuugbo gbogbo logun, Ibadan ki ba ni s’ore ai mu ni lo s’ogun. Ibadan Kure! Ibadan beere ki o too wo o, Ni bi Olè gbe n jare Olohun. B’Ibadan ti n gbonile bee lo n gba Ajoji. Eleyele lomi ti teru-tomo ‘Layipo n mu. Asejire lomi abumu-buwe nile Ibadan. A ki waye ka maa larun kan lara, Ija igboro larun Ibadan.
Authors get paid when people like you upvote their post.
If you enjoyed what you read here, create your account today and start earning FREE STEEM!
If you enjoyed what you read here, create your account today and start earning FREE STEEM!