Ni oruko Olorun Oba to kapa oohun gbogbo..

in steemit •  7 years ago 

Mo se àdúrà yii fún e ati fun gbogbo idile re, pe bi odun 2017 yii sen lo si opin, ire yii ni yio je ti e ati awon ebi re ni odun 2018

▫Ojú kò ní tì e.
▫Ayé kò ní yò e.
▫Olórun kò ní gba ògo re fún elòmíràn láéláé.
▫Igbá ilé re kò ní fó.
▫Aso ìbora re kò ní fà ya.
▫Ayé kò ní da àbàwón sí aso re.
▫Àgbá omi re kò ní gbe.
▫Kókóró ayò re kò ní bá omi lo.
▫Bí o bá n taá, á máa jó.
▫Bí o bá n lùú, á máa dún.
▫Abéré olóore re kò ni bó s'ómi.
▫Omo aráyé kò ní fi ire tìre se àpínle.
▫Bí ó ti wù kí ilé ìwòsån dára tó, oò nì fi ibe se ibùgbé.
▫Bí ó ti wù kí aso èwòn l'éwà tó, oò ní bá won wò ní'bè .
▫Won o ní fi èjè re se ìrúbo.
▫Ohun tí omo aráyé kò fi pamó sí o l'ówó, won kò ní bèèrè re l'ówóo re.
▫Omo aráyé kò ní fi egba fún o l'óúnje.
▫Bí ó ti wù kí àná ati òní re dára tó, òla re yóó l'éwà ju gbogbo won lo.
▫Orí re kò ní burú; èdá re kò ní gb'àbòdè
▫Gbogbo ibití elégbé re bá ti n ná owó, o kò ní bá won ná aájò nibe.
▫Oò ní se àsetì.
▫Wa á lu àlùyo.
▫Omo aráyé kò ní bó bàtà òfò si enu ònà iléè re.....

🏳 Aaaamin l'agbara Eledumare!

Asiko yi a tuwa lara
Ireti wa ko ni ja s'ofo.
Gbogbo igi ti elegbede ba fowo lu didun lo ndun...

▫Gbogbo adawole re yo yori si rere.
▫Gbogbo owo ti ogede ba na soke, ara re lo nfi lu kehin. Enikeni, edakeda, eeyan-keeyan ti abi ninu obinrin, abi ti a fabe gbebi e, to ba ro ibi ro e, ko fi ori ara re gbe.
▫Ilekun aanu ko ni ti mo e.
▫Ibukun ati alafia ti aye kole jakule ni yoo je ipin re.
▫Oju owo ko ni pon e.
▫Oro re yo dayo.
amin.
happy new year in advance.

image

Authors get paid when people like you upvote their post.
If you enjoyed what you read here, create your account today and start earning FREE STEEM!