Toju iwa re, ore mi;
Ola a ma si lo n'ile eni,
Ewa a si ma si l'ara enia,
Olowo oni 'nd’olosi b'o d'ola.
Okun l'ola; okun n’igbi oro,
Gbogbo won l'o nsi lo n’ile eni;
Sugbon iwa ni m’ba ni de sare’e.
Owo ko je nkan fun ni,
Iwa l'ewa omo enia.
Bi o l'owo bi o ko ni’wa nko?
Tani je f'inu tan e ba s'ohun rere?
Tabi ki o je obirin rogbodo;
Ti o ba jina si'wa ti eda nfe,
Tani je fe o s'ile bi aya?
Tabi ki o je onijibiti enia;
Bi o tile mo iwe amodaju,
Tani je gbe'se aje fun o se?
Toju Iwa re, ore mi,
Iwa ko si, eko d'egbe;
Gbogbo aiye ni 'nfe 'ni t'o je rere.
Authors get paid when people like you upvote their post.
If you enjoyed what you read here, create your account today and start earning FREE STEEM!
If you enjoyed what you read here, create your account today and start earning FREE STEEM!